ÌKÉDE KÁRÍAYÉ FÚN È̟TÓ̟ O̟MO̟NÌYÀN
Ò̟RÒ̟ ÀKÓ̟SO̟
Bí ó ti jé̟ pé s̟ís̟e àkíyèsí iyì tó jé̟ àbímó̟ fún è̟dá àti ìdó̟gba è̟tó̟ t̟̟̟̟í kò s̟eé mú kúrò tí è̟dá kò̟ò̟kan ní, ni òkúta ìpìlè̟ fún òmìnira, ìdájó̟ òdodo àti àlàáfíà lágbàáyé,
Bí ó ti jé̟ pé àìka àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn sí àti ìké̟gàn àwo̟n è̟tó̟ wò̟nyí ti s̟e okùnfà fún àwo̟n ìwà búburú kan, tó mú è̟rí-o̟kàn è̟dá gbo̟gbé̟, tó sì jé̟ pé ìbè̟rè̟ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwo̟n ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrò̟ síso̟ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wó̟n gbó̟, òmìnira ló̟wó̟ è̟rù àti òmìnira ló̟wó̟ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lo̟ ló̟kàn àwo̟n o̟mo̟-èniyàn,
Bí ó ti jé̟̟ pé ó s̟e pàtàkì kí a dáàbò bo àwo̟n è̟tó o̟mo̟nìyàn lábé̟ òfin, bí a kò bá fé̟ ti àwo̟n ènìyàn láti ko̟jú ìjà sí ìjo̟ba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ò̟nà àbáyo̟ mìíràn fún wo̟n láti bèèrè è̟tó̟ wo̟n,
Bí ó ti jé̟ pé ó s̟e pàtàkì kí ìdàgbàsókè ìbás̟epò̟ ti ò̟ré̟-sí-ò̟ré̟ wà láàrin àwo̟n orílè̟-èdè,
Bí ó ti jé̟ pé gbogbo o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé tún ti te̟nu mó̟ ìpinnu tí wó̟n ti s̟e té̟lè̟ nínú ìwé àdéhùn wo̟n, pé àwo̟n ní ìgbàgbó̟ nínú è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí, ìgbàgbó̟ nínú iyì àti è̟ye̟ è̟dá ènìyàn, àti ìgbàgbó̟ nínú ìdó̟gba è̟tó̟ láàrin o̟kùnrin àti obìnrin, tó sì jé̟ pé wó̟n tún ti pinnu láti s̟e ìgbéláruge̟ ìtè̟síwájú àwùjo̟ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé-ayé rere è̟dá ti lè gbòòrò sí i,
Bí ó ti jé̟ pé àwo̟n o̟mo̟ e̟gbé̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé ti jé̟jè̟é̟ láti fo̟wó̟s̟owó̟ pò̟ pè̟lú Àjo̟ náà, kí won lè jo̟ s̟e às̟eyege nípa àmús̟e̟ àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn àti òmìnira è̟dá tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí àti láti rí i pé à ń bò̟wò̟ fún àwo̟n è̟tó̟ náà káríayé,
Bí ó ti jé̟ pé àfi tí àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ní àmús̟e̟ è̟jé̟ yìí ní kíkún,
Ní báyìí,
Àpapò̟̟ ìgbìmò̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé s̟e ìkéde káríayé ti è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, gé̟gé̟ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo è̟dá àti orílè̟-èdè jo̟ ń lépa ló̟nà tó jé̟ pé e̟nì kò̟ò̟kan àti è̟ka kò̟ò̟kan láwùjo̟ yóò fi ìkéde yìí só̟kàn, tí wo̟n yóò sì rí i pé àwo̟n lo ètò-ìkó̟ni àti ètò-è̟kó̟ láti s̟e ìgbéláruge̟ ìbò̟wò̟ fún è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí. Bákan náà, a gbo̟dò̟ rí àwo̟n ìgbésè̟ tí ó lè mú ìlo̟síwájú bá orílè̟-èdè kan s̟os̟o tàbí àwo̟n orílè̟-èdè sí ara wo̟n, kí a sì rí i pé a fi ò̟wò̟ tó jo̟jú wo̟ àwo̟n òfin wò̟nyí, kí àmúlò wo̟n sì jé̟ káríayé láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè tó jé̟ o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan àgbáyé fúnra wo̟n àti láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè mìíràn tó wà lábé̟ às̟e̟ wo̟n.
Abala kìíní.
Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti è̟tó̟ kò̟ò̟kan sì dó̟gba. Wó̟n ní è̟bùn ti làákàyè àti ti è̟rí-o̟kàn, ó sì ye̟ kí wo̟n ó máa hùwà sí ara wo̟n gé̟gé̟ bí o̟mo̟ ìyá.
Abala kejì.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní àǹfàní sí gbogbo è̟tó̟ àti òmìnira tí a ti gbé kalè̟ nínú ìkéde yìí láìfi ti ò̟rò̟ ìyàtò̟ è̟yà kankan s̟e; ìyàtò̟ bí i ti è̟yà ènìyàn, àwò̟̟̟, ako̟-n̅-bábo, èdè, è̟sìn, ètò ìs̟èlú tàbí ìyàtò̟ nípa èrò e̟ni, orílè̟-èdè e̟ni, orírun e̟ni, ohun ìní e̟ni, ìbí e̟ni tàbí ìyàtò̟̟ mìíràn yòówù kó jé̟. Síwájú sí i, a kò gbo̟dò̟ ya e̟nìké̟ni só̟tò̟ nítorí irú ìjo̟ba orílè̟-èdè rè̟ ní àwùjo̟ àwo̟n orílè̟-èdè tàbí nítorí ètò-ìs̟èlú tàbí ètò-ìdájó̟ orílè̟-èdè rè̟; orílè̟-èdè náà ìbáà wà ní òmìnira tàbí kí ó wà lábé̟ ìs̟àkóso ilè̟ mìíràn, wo̟n ìbáà má dàá ìjo̟ba ara wo̟n s̟e tàbí kí wó̟n wà lábé̟ ìkáni-lápá-kò yòówù tí ìbáà fé̟ dí òmìnira wo̟n ló̟wó̟ gé̟gé̟ bí orílè̟-èdè.
Abala ke̟ta.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti wà láàyè, è̟tó̟ sí òmìnira àti è̟tó̟ sí ààbò ara rè̟.
Abala ke̟rin.
A kò gbo̟dò̟ mú e̟niké̟ni ní e̟rú tàbí kí a mú un sìn; e̟rú níní àti ò wò e̟rú ni a gbo̟dò̟ fi òfin dè ní gbogbo ò̟nà.
Abala karùn-ún.
A kò gbo̟dò̟ dá e̟nì ké̟ni lóró tàbí kí a lò ó ní ìlò ìkà tí kò ye̟ o̟mo̟ ènìyàn tàbí ìlò tó lè tàbùkù è̟dá ènìyàn.
Abala ke̟fà.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a kà á sí gé̟gé̟ bí ènìyàn lábé̟ òfin ní ibi gbogbo.
Abala keje.
Gbogbo ènìyàn ló dó̟gba lábé̟ òfin. Wó̟n sì ní è̟tó̟ sí àà bò lábé̟ òfin láìsí ìyàsó̟tò̟ kankan. Gbogbo ènìyàn ló ní è̟tó̟ sí ààbò tó dó̟gba kúrò ló̟wó̟ ìyàsó̟tò̟ yòówù tí ìbáà lòdì sí ìkéde yìí àti è̟tó̟ kúrò ló̟wó̟ gbogbo ohun tó bá lè ti ènìyàn láti s̟e irú ìyàsó̟tò̟ bé̟è̟.
Abala ke̟jo̟.
E̟nì kò̟ò̟kan lórílè̟-èdè, ló ní è̟tó̟ sí àtúns̟e tó jo̟jú ní ilé-e̟jó̟ fún ìwà tó lòdì sí è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí gé̟gé̟ bó s̟e wà lábé̟ òfin àti bí òfin-ìpìlè̟ s̟e là á sílè̟.
Abala ke̟sàn-án.
A kò gbo̟dò̟ s̟àdédé fi òfin mú ènìyàn tàbí kí a kàn gbé ènìyàn tì mó̟lé, tàbí kí a lé ènìyàn jáde ní ìlú láìnídìí.
Abala ke̟wàá.
E̟nì kò̟ò̟kan tí a bá fi è̟sùn kàn ló ní è̟tó̟ tó dó̟gba, tó sì kún, láti s̟àlàyé ara rè̟ ní gban̅gba, níwájú ilé-e̟jó̟ tí kò s̟ègbè, kí wo̟n lè s̟e ìpinnu lórí è̟tó̟ àti ojús̟e rè̟ nípa irú è̟sùn ò̟ràn dídá tí a fi kàn án.
Abala ko̟kànlá.
- E̟nìké̟ni tí a fi è̟sùn kàn ni a gbo̟dò̟ gbà wí pé ó jàrè títí è̟bi rè̟ yóò fi hàn lábé̟ òfin nípasè̟ ìdájó̟ tí a s̟e ní gban|gba nínú èyí tí e̟ni tí a fi è̟sùn kàn yóò ti ní gbogbo ohun tí ó nílò láti fi s̟e àwíjàre ara rè̟.
- A kò gbo̟dò̟ dá è̟bi è̟s̟è̟ fún e̟nìké̟ni fún pé ó hu ìwà kan tàbí pé ó s̟e àwo̟n àfojúfò kàn nígbà tó jé̟ pé lásìkò tí èyí s̟e̟lè̟, irú ìwà bé̟è̟ tàbí irú àfojúfò bé̟è̟ kò lòdì sí òfin orílè̟-èdè e̟ni náà tàbí òfin àwo̟n orílè̟-èdè àgbáyé mìíràn. Bákan náà, ìje̟níyà tí a lè fún e̟ni tó dé̟s̟è̟ kò gbo̟dò̟ ju èyí tó wà ní ìmúlò ní àsìkò tí e̟ni náà dá è̟s̟è̟ rè̟.
Abala kejìlá.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a má s̟àdédé s̟e àyo̟júràn sí ò̟rò̟ ìgbésí ayé rè̟, tàbí sí ò̟rò̟e̟bí rè̟ tàbí sí ò̟rò̟ ìdílé rè̟ tàbí ìwé tí a ko̟ sí i; a kò sì gbo̟dò̟ ba iyì àti orúko̟ rè̟ jé̟. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ààbò lábé̟ òfin kúrò ló̟wó̟ irú àyo̟júràn tàbí ìbanijé̟ bé̟è̟.
Abala ke̟tàlá.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti rìn káàkiri ní òmìnira kí ó sì fi ibi tó bá wù ú s̟e ìbùgbé láàrin orílè̟-èdè rè̟.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti kúrò lórílè̟-èdè yòówù kó jé̟, tó fi mó̟ orílè̟-èdè tirè̟, kí ó sì tún padà sí orílè̟-èdè tirè̟ nígbà tó bá wù ú.
Abala ke̟rìnlá.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti wá ààbò àti láti je̟ àn fàní ààbò yìí ní orílè̟-èdè mìíràn nígbà tí a bá ń s̟e inúnibíni sí i.
- A kò lè lo è̟tó̟ yìí fún e̟ni tí a bá pè lé̟jó̟ tó dájú nítorí e̟ s̟̟è̟ tí kò je̟ mó̟ ò̟rò̟ ìs̟èlú tàbí ohun mìíràn tí ó s̟e tí kò bá ète àti ìgbékalè̟ Ajo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé mu.
Abala ke̟è̟é̟dógún.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti jé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè kan.
- A kò lè s̟àdédé gba è̟tó̟ jíjé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè e̟ni ló̟wó̟ e̟nìké̟ni láìnídìí tàbí kí a kò̟ fún e̟nìké̟ni láti yàn láti jé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè mìíràn.
Abala ke̟rìndínlógún.
- To̟kùnrin tobìnrin tó bá ti bàlágà ló ní è̟tó̟ láti fé̟ ara wo̟n, kí wó̟n sì dá e̟bí ti wo̟n sílè̟ láìsí ìkanilápá-kò kankan nípa è̟yà wo̟n, tàbí orílè̟-èdè wo̟n tàbí è̟sìn wo̟n. E̟tó̟ wo̟n dó̟gba nínú ìgbeyàwó ìbáà jé̟ nígbà tí wo̟n wà papò̟ tàbí lé̟yìn tí wó̟n bá ko̟ ara wo̟n.
- A kò gbo̟dò̟ s̟e ìgbeyàwó kan láìjé̟ pé àwo̟n tí ó fé̟ fé̟ ara wo̟n ní òmìnira àto̟kànwá tó péye láti yàn fúnra wo̟n.
- E̟bí jé̟ ìpìlè̟ pàtàkì àdánidá ní àwùjo̟, ó sì ní è̟tó̟ pé kí àwùjo̟ àti orílè̟-èdè ó dáàbò bò ó.
Abala ke̟tàdínlógún.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti dá ohun ìní ara rè̟ ní tàbí láti ní in papò̟ pè̟lú àwo̟n mìíràn.
- A kò lè s̟àdédé gba ohun ìní e̟nì kan ló̟wó̟ rè̟ láìnídìí.
Abala kejìdínlógún.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟̟tó̟ sí òmìnira èrò, òmìnira è̟rí-o̟kàn àti òmìnira e̟ sìn. E̟tó̟ yìí sì gbani láàyè láti pààrò̟ e̟ sìn tàbí ìgbàgbó̟ e̟ni. Ó sì fún e̟yo̟ e̟nì kan tàbí àkójo̟pò̟ ènìyàn láàyè láti s̟e è̟sìn wo̟n àti ìgbàgbó̟ wo̟n bó s̟e je̟ mó̟ ti ìkó̟ni, ìs̟esí, ìjó̟sìn àti ìmús̟e ohun tí wó̟n gbàgbó̟ yálà ní ìkò̟kò̟ tàbí ní gban̅gba.
Abala ko̟kàndínlógún.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí òmì nira láti ní ìmò̟ràn tí ó wù ú, kí ó sì so̟ irú ìmò̟ràn bé̟è̟ jáde; è̟tó̟yìí gbani láàyè láti ní ìmò̟ràn yòówù láìsí àtakò láti ò̟dò̟ e̟nìké̟ni láti wádìí ò̟rò̟, láti gba ìmò̟ràn ló̟dò̟ e̟lòmíràn tàbí láti gbani níyànjú ló̟nàkó̟nà láìka ààlà orílè̟-èdè kankan kún.
Abala ogún.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí òmìnira láti pé jo̟ pò̟ àti láti dara pò̟ mó̟ àwo̟n mìíràn ní àlàáfíà.
- A kò lè fi ipá mú e̟nìké̟ni dara pò̟ mó̟ e̟gbé̟ kankan.
Abala ko̟kànlélógún.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟̟tó̟ láti kópa nínú ìs̟àkóso orílè̟-èdè rè̟, yálà fúnra rè̟ tàbí nípasè̟ àwo̟n as̟ojú tí a kò fi ipá yàn.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ tó dó̟gba láti s̟e is̟é̟ ìjo̟ba ní orílè̟-èdè rè̟.
- I fé̟ àwo̟n ènìyàn ìlú ni yóò jé̟ òkúta ìpìlè̟ fún à s̟e̟ ìjo̟ba; a ó máa fi ìfé̟ yìí hàn nípasè̟ ìbò tòótó̟ tí a ó máa dì láti ìgbà dé ìgbà, nínú èyí tí e̟nì kò̟ò̟kan yóò ní è̟tó̟ sí ìbò kan s̟os̟o tí a dì ní ìkò̟kò̟ tàbí nípasè̟ irú o̟ nà ìdìbò mìíràn tí ó bá irú ìdìbò bé̟è̟ mu.
Abala kejìlélógún.
E̟nì kò̟ò̟kan gé̟gé̟̟ bí è̟yà nínú àwùjo̟ ló ní è̟tó̟ sí ìdáàbò bò láti o̟wó̟ ìjo̟ba àti láti jé̟ àn fà ní àwo̟n è̟tó̟ tí ó bá o̟rò̟-ajé, ìwà láwùjo̟ àti às̟à àbínibí mu; àwo̟n è̟tó̟ tí ó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí fún iyì àti ìdàgbàsókè è̟dá ènìyàn, nípa akitiyan nínú orílè̟-èdè àti ìfo̟wó̟s̟owó̟ pò̟ láàrin àwo̟n orílè̟-èdè ní ìbámu pè̟lú ètò àti ohun àlùmó̟nì orílè̟-èdè kò̟ò̟kan.
Abala ke̟tàlélógún.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti s̟is̟é̟, láti yan irú is̟é̟ tí ó wù ú, lábé̟ àdéhùn tí ó tó̟ tí ó sì tún ro̟rùn, kí ó sì ní ààbò kúrò ló̟wó̟ àìrís̟é̟ s̟e.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti gba iye owó tí ó dó̟gba fún irú is̟é̟ kan náà, láìsí ìyàsó̟tò̟ kankan.
- E̟nì kò̟ò̟kan tí ó bá ń s̟isé̟ ní è̟tó̟ láti gba owó os̟ù tí ó tó̟ tí yóò sì tó fún òun àti e̟bí rè̟ láti gbé ayé tí ó bu iyì kún ènìyàn; a sì lè fi kún owó yìí nípasè̟ orís̟ìí àwo̟n ètò ìrànló̟wó̟ mìíràn nígbà tí ó bá ye.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti dá e̟gbé̟ òs̟ìs̟é̟ sílè̟ àti láti dara pò̟ mó̟ irú e̟gbe̟; bé̟è̟ láti dáàbò bo àwo̟n ohun tí ó je̟ é̟ lógún.
Abala ke̟rìnlélógún.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ìsinmi àti fàájì pè̟lú àkókò tí kò pò̟ jù lé̟nu is̟é̟ àti àsìkò ìsinmi lé̟nu is̟é̟ láti ìgbà dé ìgbà tí a ó sanwó fún.
Abala ke̟è̟é̟dó̟gbò̟n.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu nínú èyí tí òun àti e̟bí rè̟ yóò wà ní ìlera àti àlàáfíà, tí wo̟n yóò sì ní oúnje̟, as̟o̟, ilégbèé, àti àn fàní fún ìwòsàn àti gbogbo ohun tó lè mú è̟dá gbé ìgbé ayé rere. Bákan náà, e̟nì kò̟ò̟kan ló tún ní ààbò nígbà àìnís̟é̟ló̟wó̟, nígbà àìsà n, nígbà tó bá di aláàbò̟-ara, ní ipò opó, nígbà ogbó rè̟ tàbí ìgbà mìíràn tí ènìyàn kò ní ò̟nà láti rí oúnje̟ òò jó̟, tí eléyìí kì í sì í s̟e è̟bi olúwa rè̟.
- A ní láti pèsè ìtó̟jú àti ìrànló̟wó̟ pàtàkì fún àwo̟n abiyamo̟ àti àwo̟n o̟mo̟dé. Gbogbo àwo̟n o̟mo̟dé yóò máa je̟ àwo̟n àn fàní ààbò kan náà nínú àwùjo̟ yálà àwo̟n òbí wo̟n fé̟ ara wo̟n ni tàbí wo̟n kò fé̟ ara wo̟n.
Abala ke̟rìndínló̟gbò̟n.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti kó̟ è̟kó̟. Ó kéré tán, è̟kó̟ gbo̟dò̟ jé̟ ò̟fé̟ ní àwo̟n ilé-è̟kó̟ alákò̟ó̟bè̟rè̟. E̟kó̟ ní ilé-è̟kó̟ alákò̟ó̟bè̟rè̟ yìí sì gbo̟dò̟ jé̟ dandan. A gbo̟dò̟ pèsè è̟kó̟ is̟é̟-o̟wó̟, àti ti ìmò̟-è̟ro̟ fún àwo̟n ènìyàn lápapò̟. Àn fàní tó dó̟gba ní ilé-è̟kó̟ gíga gbo̟dò̟ wà ní àró̟wó̟tó gbogbo e̟ni tó bá tó̟ sí.
- Ohun tí yóò jé̟ ète è̟kó̟ ni láti mú ìlo̟síwájú tó péye bá è̟dá ènìyàn, kí ó sì túbò̟ rí i pé àwo̟n ènìyàn bò̟wò̟ fún è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn àti àwo̟n òmìnira wo̟n, tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí. E tò è̟kó̟ gbo̟dò̟ lè rí i pé è̟mí; ìgbó̟ra-e̟ni-yé, ìbágbépò̟ àlàáfíà, àti ìfé̟ ò̟ré̟-sí-ò̟ré̟ wà láàrin orílè̟-èdè, láàrin è̟yà kan sí òmíràn àti láàrin e̟lé̟sìn kan sí òmíràn. E tò-è̟kó̟ sì gbo̟dò̟ kún àwo̟n akitiyan Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé ló̟wó̟ láti rí i pé àlàáfíà fìdí múlè̟.
- Àwo̟n òbí ló ní è̟tó̟ tó ga jù lo̟ láti yan è̟kó̟ tí wó̟n bá fé̟ fún àwo̟n o̟mo̟ wo̟n.
Abala ke̟tàdínló̟gbò̟n.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láìjé̟ pé a fi ipá mú un láti kópa nínú àpapò̟ ìgbé ayé àwùjo̟ rè̟, kí ó je̟ ìgbádùn gbogbo ohun àmús̟e̟ wà ibè̟, kí ó sì kópa nínú ìdàgbàsókè ìmò̟ sáyé̟n sì àti àwo̟n àn fàní tó ń ti ibè̟ jáde.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ààbò àn fàní ìmo̟yì àti ohun ìní tí ó je̟ yo̟ láti inú is̟é̟ yòówù tí ó bá s̟e ìbáà s̟e ìmò̟ sáyé̟n sì, ìwé kíko̟ tàbí is̟é̟ o̟nà.
Abala kejìdínló̟gbò̟n.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ètò nínú àwùjo̟ rè̟ àti ní gbogbo àwùjo̟ àgbáyé níbi tí àwo̟n è̟tó̟ òmìnira tí a ti gbé kalè̟ nínú ìkéde yìí yóò ti jé̟ mímús̟e̟.
Abala ko̟kàndínló̟gbò̟n.
- E̟nì kò̟ò̟kan ló ní àwo̟n ojús̟e kan sí àwùjo̟, nípasè̟ èyí tí ó fi lè s̟eé s̟e fún e̟ni náà láti ní ìdàgbàsókè kíkún gé̟gé̟ bí è̟dá ènìyàn.
- O fin yóò de e̟nì kò̟ò̟kan láti fi ò̟wò̟ àti ìmo̟yì tí ó tó̟ fún è̟tó̟ àti òmìnira àwo̟n e̟lòmíràn nígbà tí e̟ni náà bá ń lo àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira ara rè̟. E yí wà ní ìbámu pè̟lú ò̟nà tó ye̟, tó sì tó̟ láti fi báni lò nínú àwùjo̟ fún ire àti àlàáfíà àwùjo̟ náà nínú èyí tí ìjo̟ba yóò wà ló̟wó̟ gbogbo ènìyàn.
- A kò gbo̟dò̟ lo àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí rárá, ní ò̟nà yòówù kó jé̟, tó bá lòdì sí àwo̟n ète àti ìgbékalè̟ Ajo̟-àpapò̟ orílè̟-èdè agbáyé.
Abala o̟gbò̟n.
A kò gbo̟dò̟ túmò̟ ohunkóhun nínú ìkéde yìí gé̟gé̟ bí ohun tí ó fún orílè̟-èdè kan tàbí àkójo̟pò̟ àwo̟n ènìyàn kan tàbí e̟nìké̟ni ní è̟tó̟ láti s̟e ohunkóhun tí yóò mú ìparun bá èyíkéyìí nínú àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira tí a kéde yìí.